GOODLUCK JONATHAN KO LẸTỌ LATI JADE DU IPO AARẸ ORILẸ-EDE YII MỌ - ỌNỌJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 22, 2020

GOODLUCK JONATHAN KO LẸTỌ LATI JADE DU IPO AARẸ ORILẸ-EDE YII MỌ - ỌNỌJA


Laipẹ yii l'awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ṣe ipade pọ pẹlu Aarẹ ana, Goodluck Ebele Jonathan nilu Abuja, nibi t'awọn kan ti n sọ pe imurasilẹ iàdabọ Jọnathan gẹgẹ bi Aarẹ ni wọn ṣe ipade le lori.
 
 
Bẹ o ba gbagbe, ọdun 2011 ni wọn dibo yan Goodluck Jonathan, to si pada sọwọ Aarẹ Buhari ninu idibo ọdun 2015. 
 
Awuyewuye to n jade latigba t'awọn Gomina yii ti ṣe ipade pọ pẹlu Jonathan ni pe o ṣi yẹ lẹni to le jade du ipo Aarẹ orilẹ-ede yii nitori pe ẹẹkan ṣoṣo pere lo ṣi ṣe gẹgẹ bi Aarẹ.
 
Ṣugbọn ohun táwọn kan n sọ bayii ni pe Jonathan ko ni anfaani lati jade du ipo Aarẹ lorilẹ-ede yii nitori pe funra rẹ lo sọ ọ di ofin wi pe awọn igbakeji Aarẹ ati igbakeji Gomina ti wọn ba pari iṣakoso saa ọga wọn ko lanfaani lati du ipo lẹẹkeji.

Ọkan lara awọn agbẹjọro orilẹ-ede yii, Ilemona Onoja to f'ilu Abuja ṣe ibugbe sọ pe Jonatha naa ko lanfaani lati jade du ipo kankan mọ nitori pe ofin to gbe kalẹ nigba naa ṣi wa nilẹ.
 
Onoja ni bi wọn yoo ba tiẹ gbe ofin naa yẹwo, ti wọn si pinnu lati ṣe atunṣe rẹ, yoo nilo awọn ipinlẹ ti ko din ni mẹrindinlogun lati fimọ-ṣọkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI