AṢIRI BI WỌN ṢE RA DUKIA IJỌBA KWARA LU SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 22, 2020

AṢIRI BI WỌN ṢE RA DUKIA IJỌBA KWARA LU SITAỌkan lara awọn kọmiṣanna tẹlẹri n'ipinlẹ Kwara, Ọnọrebu Sulaiman Kayọde Yusuf ti tu aṣiri bo ṣe ra dukia ijọba funra rẹ, to si n lo o lati ọdun 2014.

Iwaju igbimọ to n ṣe iwadii b'awọn ijọba to kọja lọ ṣe ta awọn dukia ijọba lọna aitọ, eyi ti Onidajọ Ọlabanji Orilonishe jẹ alaga rẹ ni Ọnọrebu Orilonishe t'awọn eeyan tun n pe ni Maja ti tu aṣiri naa.

Maja ni ọdun 2003 ni ijọba ipinlẹ naa f'oun ni dukia naa lati maa gbe gẹgẹ bi ọkan lara awọn kọmiṣanna, ati pe dukia naa ko ni orule at'awọn nnkan amayedẹrun ninu rara, to si loun loun tun un ṣe.

O ni ọdun 2004 loun pinnu lati ra dukia naa ti wọn pe ni Chalet, iyẹn awọn ile t'ijọba kọ f'awọn alejo ti wọn ba gba pẹlu erongba lati din owo otẹẹli gbigba ku, to si ni miliọnu mẹsan din lẹgbẹrun lọna igba (8.8m) naira ni wọn ta a f'oun.

Maja ni lati ọdun 2004 toun ti san owo dukia naa, inu oṣu kẹta ọdun 2016 ni wọn ṣẹṣẹ gbe iwe ẹ f'oun, to si latigba toun ti wa nibẹ loun ti n gbe nibẹ.

Ọkunrin naa to tun ti f'igba kan ri jẹ alaga ileeṣẹ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ, iyẹn Local Government Service Commission naa wa bẹ igbimọ naa lati wo ipo ailera toun wa, ki wọn wa ibomin in f'oun lati gbe ko to di pe wọn gba a lọwọ oun.
 
Lẹyin eyi laṣiri tun tu pe Ọnọrebu Maja n lo awọn mọto meji kan to ni nọmba idanimọ t'ijọba ipinlẹ naa ninu, to si ni ijọba lo gbe bọọsi kan f'oun lasiko ipolongo eto idibo, ati pe ijọba tun ta mọto kan yooku f'oun lowo pọọku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI