Ọkan awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ giga gbogboniṣe ti Nuhu Bamali to wa n'ipinlẹ Kaduna ko balẹ rara lasiko ti a ṣakojopọ iroyin yii tan lori b'awọn ajinigbe ṣe ji ọkan lara awọn olukọni wọn gbe.
Akọwe iroyin ile-ẹkọ gbogboniṣe naa, Ọgbẹni Abdullahi Shehu lo f''idi ọrọ naa mulẹ f'awọn oniroyin lonii ọjọ Aiku ti i ṣe Sannde.
Ọkunrin naa ni inu ile ti wọn n gbe, eyi to wa ninu ọgba ile-ẹkọ naa ni wọn ti ji olukọ wọn to wa ni ẹka ikẹkọọ imọ ẹrọ, iyẹn School of Engineering at'awọn ọmọ kekeeke meji naa gbe.
O tun jẹ ko di mimọ pe baba awọn ọmọ meji ti wọn ji gbe yii l'awọn ajinigbe fi ibọn fọ lori, to si l'awọn eeyan ti gbe e lọ si ọsibitu fun itọju.
No comments:
Post a Comment