NIBI TI DỌKITA TI N ṢAYẸWO LARA IYAALE ILE LO TI KO IBASUN FUN UN KARAKARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 14, 2020

NIBI TI DỌKITA TI N ṢAYẸWO LARA IYAALE ILE LO TI KO IBASUN FUN UN KARAKARA


Ọrọ buruku t'oun tẹrin nile ẹjọ majisireeti to wa nilu Adamawa, ipinlẹ Yola n'igba wọn foju dọkita kan han niwaju adajọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni dọkita naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Phillips Duru ko ibasun fun iyaale ile kan ta a forukọ bo laṣiri karakara lasiko to n ṣayẹwo fun un.
 
Wọn ni iyaale ile naa lo lọ si ọsibitu Phillips lati ṣe ayẹwo ara rẹ, ọsibitu naa la gbọ pe o wa nitọsi ọsibitu ijọba, iyẹn Adamawa State Specialist Hospital, iyẹn nibi ti Phillips tun ti n gba owo oṣu.
 
Awọn to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe bi obinrin naa ṣe debẹ, to ṣalaye awọn nnkan to n ṣapẹrẹ lara rẹ fun Phillips, lo ti sọ pe ko sun sori bẹẹdi to wa ninu ọfiisi ẹ. Bi obinrin naa ṣe sun ni wọn sọ pe Phillips ti tọwọ bọ nnkan ọmọbinrin ẹ, to si ni ko bọ pata ẹ.
 
Wọn ni bi obinrin naa ṣe bọ pata ni Phillips ti sare yọ kondo abẹ rẹ jade, to si fi ba obinrin naa laṣepọ.
 
Igba ti wọn ni Phillips tẹ ara rẹ lọrun lo to fi obinrin naa silẹ, ti wọn si ni ṣe lobinrin naa gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi ẹjọ sun wọn, t'awọn ọlọpaa si lọ gbe Phillips.
 
Adajọ ile ẹjọ naa la gbọ pe o ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI