IDIBO AARẸ 2023: ẸGBẸ OSELU APC SỌRỌ LORI IPOLONGO AMEACHI ATI EL-RUFAI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 4, 2020

IDIBO AARẸ 2023: ẸGBẸ OSELU APC SỌRỌ LORI IPOLONGO AMEACHI ATI EL-RUFAI


Laipẹ yii ni alẹmode ipolongo idibo Aarẹ kan gba igboro orilẹ-ede Naijiria, nibi ti Gomina ipinlẹ Kaduna ti n dije du ipo Aarẹ, ti minisita fọrọ igbokegbodo ọkọ, Rotimi Ameachi ti jẹ igbakeji rẹ.


Iyalẹnu nla gbaa ni alẹmode ipolongo naa jẹ f'awọn to ṣalabapade ẹ, ti wọn si gbe e sori ikanni ayelujara wi pe awọn mejeeji yii ti ṣetan lati gba ipo lọwọ Aarẹ Buhari lọdun 2023.


Ninu alẹmode ipolongo naa ni wọn ti kọ ọ sibẹ pe awọn mejeeji naa l'awọn ọmọ Naijiria n fẹ, ati pe bi ko ba jẹ asiko yii, asiko naa n bọ laipẹ lati jẹ aṣaaju wọn l'ọdun 2023.


Ṣugbọn ni kete ti awọn alẹmode ipolongo naa tẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives COngress, iyẹn APC lọwọ ni agbẹnusọ wọn , Yẹkini Nabena ti sọrọ sita wi pe awọn oludije mejeeji naa ko ti i fi to awọn leti wi pe ipo naa wu awọn lati du l'ọdun 2023.


Iwaju ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere, iyẹn Ministry of Foreign Affairs at'awọn agbegbe kan nilu Abuja ni wọn lẹ awọn alẹmode naa si i.


Nabena tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe awọn yoo ṣe iwadii awọn to wa lẹyin alẹmode naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI