Kani kí i ṣe ẹ̀mí Ọlọ́run tó wà lára gbajumọ pasitọ nnì, Pasitọ Lawrence Achudumẹ to ni ṣọọṣi Victory Life Bible Church ni, ó ṣeé ṣe kó bínú jáde níbi ìpàdé àwọn ọdọ tó wáyé ní gbọngan àṣà tí June 12 tó wà n'ilu Abẹ́òkúta lónìí, ṣùgbọ́n tó fi tí Àmì Òróró gbe e.
Pupọ àwọn tó wà níbi àkànṣe eto naa ni wọn ń bù ẹnu atẹ lu ìwà tí Gómìnà Dapọ Abiọdun hu sì Pasitọ Achudumẹ lásìkò tí eto naa n lọ.
Àwọn ọdọ kan ni wọn gbé eto kan kalẹ tí wọ́n pè ní Ogun Youth-Government Townhall Meeting kalẹ láti fi saami ayẹyẹ ọjọ́ àwọn ọdọ lagbaye.
Nibi eto naa ti wọn pé àkòrí ẹ ní 'Youth, Skills and Insecurity: Connections, Costs and Opportunities' ni wọn ti pé àwọn ọtọkulu àtàwọn amòye láwùjọ láti ṣe idanilẹkọọ fáwọn akopa.
Pasitọ Lawrence Achudumẹ náà kò gbẹyin nínú àwọn tí wọn pé láti sọ̀rọ̀ nibi eto tó ṣì ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tá a fi kọ ìròyìn yìí tán.
AWIKONKO gbọ pé lẹ́yìn tí Pasitọ Achudumẹ parí ọ̀rọ̀ rẹ tó sì gba àwọn ọdọ lamọran wí pé kí wọn tún èrò ọkàn wọn pá láti lè dé ibi gíga láyé, tó sì fi ọkàn lára àwọn amugbalẹgbẹ gómìnà ìyẹn Ọlamide Lawal ṣe àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ọdọ tó ní ọjọ́ iwájú réré.
Wọn ní bo ṣe ṣetan láti máa lọ lo gbìyànjú láti kí Gómìnà Dapọ Abiọdun níbi tó jókòó sí pẹ̀lú ibọlọwọ.
Àwọn tó gbé ìròyìn náà sì wà létí je ko ye wá pé bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà ṣe nọwọ sì Gómìnà láti kí í kú iṣẹ takuntakun ni Gómìnà yẹ ọwọ fún un, tó sì fi igunpa pàdé rẹ.
Bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀ làwọn tó wà níbẹ̀ tí bẹ̀rẹ̀ si í kún sínú pé ìwà tí Gomina hu kú díẹ̀ kaato, àti pé kò yẹ kí Gómìnà ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.
Ohun táwọn kan ń sọ ní pe bí Gómìnà bá tiẹ̀ ń sá láti kó àrùn koronafairọọsi, ìyẹn COVID-19, èyí tó mú kó máa sá láti bọ àwọn èèyàn lọ́wọ́, wọn ní kó yẹ kó jẹ́ irú ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ pé ó lójú àwọn tó ń rí wọn.
No comments:
Post a Comment