IDIBO AMẸRIKA: AWỌN EEYAN YẸYẸ TARIBO WEST LORI ASỌTẸLẸ RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 10, 2020

IDIBO AMẸRIKA: AWỌN EEYAN YẸYẸ TARIBO WEST LORI ASỌTẸLẸ RẸ


Asiko yii ki i ṣe asiko to rọrun fun gbajugba agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ nni, Taribo West lori b'awọn eeyan ṣe n da ọrọ buruku bo o lori asọtẹlẹ ti wọn lo o sọ nipa idibo ilẹ Amẹrika to waye l'ọsẹ to kọja, nibi ti wọn lo o ti sọ pe Donald Trump ni yoo pada jawe olubori.
 
Taribo West ni wọn lo o sọ pe pẹlu maaki perete ni Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump yoo fi bori alatako rẹ, Joe Biden ninu eto idibo naa, ṣugbọn to pada jẹ pe Biden lo gbegba oroke.
 
Taribo to loun ti sọ asọtẹlẹ rere, to si ti wa si imuṣẹ, paapaa nipa idibo ipinlẹ Ẹdọ wi pe Godwin Ọbasẹki ni yoo pada wọle; bẹẹ naa ni pe Gomina Rotimi Akeredolu ni yoo jawe olubori n'ipinlẹ Ondo.
 
Fidio naa nibi ti Taribo West ti n sọ asọtẹlẹ yii lo jade sori ikanni ayelujara ki idibo naa to waye, ṣugbọn to pada tan kaakiri lẹyin ti wọn pari eto idibo naa, t'awọn eeyan si n sọ pe ayederu asọtẹlẹ ni ọkunrin naa sọ jade.
 
Lasiko to n sọrọ naa lo tun ti bẹ awọn ọmọ ijọ rẹ wi pe ki wọn jẹ ki ọrọ rẹ naa tan kaakiri agbaye, k'awọn eeyan le ri i pe Ọlọrun lo ran oun niṣẹ toootọ, ki i ṣe pe oun n jiṣẹ ara oun.

Bi wọn ṣe kede Joe Biden gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori l'awọn eeyan ti bẹrẹ si i sọrọ buruku si Taribo West, ti wọn si n ṣẹlẹya pe ko lọ jokoo ara rẹ, nitori pe iṣẹ ara rẹ lo n jẹ, ki i ṣe iṣẹ Ọlọrun, ati pe okiki lo n wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI