WỌN DAJỌ IKU F'AWỌN MẸTA L'EKITI ATI OGUN LORI ẸSUN IDIGUNJALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 10, 2020

WỌN DAJỌ IKU F'AWỌN MẸTA L'EKITI ATI OGUN LORI ẸSUN IDIGUNJALE


Ile ẹjọ giga to wa nilu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti ti da ẹjọ iku f'awọn baale ile meji kan, Ọkẹ Ọlanrewaju ati Ọlanbiwọninu Kazeem lori ẹsun idigunjale, bẹẹ ni ile ẹjọ giga kan to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun da ẹjọ iku fun Jẹlili Agẹmọ lori ẹsun kan naa.
 
Ana ti i ṣe Mọnde, iyẹn ọjọ Aje l'awọn idajọ yii waye.
 
Ọlanrewaju, ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) ati Kazeem, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn la gbọ pe awọn ọlọpaa f'ẹsun idigunjale kan l'ogunjọ oṣu keje ọdun 2016.

Wọn i ṣe l'awọn mejeeji yii loọ digun jale lojule keji, adugbo Ameen, Federal Housing, Oke-Ila, ilu Ado-Ekiti, lọjọ naa ni wọn tun ja ẹni kan ti wọn pe ni Alaaji Ameen Rasheed lole awọn dukia ẹ, to fi mọ foonu olowo iyebiye.

Lẹyin eyi ni wọn tun digun ja ẹnikan ti wọn pe ni Ọlaoti Abiọdun lole owo ati oriṣiriṣi foonu olowo nla, ta a si gbọ pe awọn ẹsun yii tako ofin ọdaran ipinlẹ naa t'ọdun 2012.
 
AWIKONKO gbọ pe awọn meje ọtọọtọ ni wọn jẹri tako awọn mejeeji naa, idi ti Onidajọ naa, Lekan Ogunmoye fi paṣẹ pe ẹjọ iku lo tọ si wọn lai ni ẹbẹ kankan ninu, to si ni ki wọn lọ yegi fun wọn.
 
Jẹlili Agẹmọ, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni tiẹ la gbọ pe ẹsun mẹta ọtọọọtọ ni wọn fi kan oun to ni i ṣe pẹlu idigunjale ati lilo ibọn lọna ti ko tọ.
 
A gbọ pe ọjọ kẹwaa ati ọjọ kẹrinla oṣu kẹwaa ọdun 2009 ni Jẹlili digun jale ladugbo Majekembo to wa lagbegbe Quarry Road, Abẹokuta. Wọn ni awọn yooku ti wọn jọ jale pẹlu Jẹlili ti na papa bora, ti ọwọ ko si ti i ba wọn titi di asiko ti wọn da ẹjọ naa.
 
Awọn mẹfa ọtọọtọ la gbọ pe wọn digun ja lole l'awọn ọjọ yii, lara wọn si ni Arabinrin Adeile Kẹmi, Arabinrin Adegbe Grace, Dọkita O. O. Dipeolu, Arabinrin Ọlakunle Olubukọla, Ṣeun Adelano ati Ọṣhọ Mercy.
 
Oriṣiriṣi dukia bi i foonu, ẹṣọ, ẹrọ kọmputa alagbeeka at'awọn nnkan mi in ni wọn digun gba lọjọ naa, eyi ti wọn lo o tako ẹsun ọdaran ipinlẹ Ogun ti ọdun 2004.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Abiọdun Akinyẹmi sọ pe awọn ẹri iwaju oun kọja sisọ, to bẹẹ to fi ni idajọ iku lo tọ si Jẹlili, ati pe yoo tun ṣẹwọn ọdun mẹwaa lori ibọn to n lo lai lẹtọọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI