IKUNLẸ ABIYAMỌ O! WỌN PA ỌMỌ ỌDUN MẸFA DANU L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 24, 2020

IKUNLẸ ABIYAMỌ O! WỌN PA ỌMỌ ỌDUN MẸFA DANU L'ABẸOKUTA


Ẹkun ayeraye l'awọn oniṣẹ ibi kan ju sinu idile kan n'ilu Abẹokuta l'ọsẹ to kọja yii lori bi wọn ṣe pa ọmọ wọn kan to jẹ ọmọ ọdun mẹfa danu, ti wọn si lọ ju oku ẹ seti odo.
 
AWIKONKO gbọ pe ibi ti ọmọ naa ti n ṣere pẹlu awọn ọrẹ rẹ niwaju ita ile wọn la gbọ pe ọmọ naa ti d'awati, ti ko si sẹni to le sọ bo ṣe rin in.
 
Adugbo kan ti wọn n pe ni Ṣodẹkẹ to wa n'ilu ABẹokuta, ipinlẹ Ogun n'iṣẹlẹ naa ti waye gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
 
Hassan Adefuyi ni wọn pe orukọ ọmọ naa, ti wọn si sọ pe ko pẹ to de lati ileewe lo jẹun, to si lọ n b'awọn ọrẹ rẹ ṣere ki iṣẹlẹ buruku naa to o ṣẹlẹ.
 
Wọn ni gbogbo akitiyan awọn ara agbegbe naa lati ri Hassan lo ja si pabo lati nnkan bi aago kan ọsan ọjọ naa, to si jẹ pe aarọ kutu ọjọ keji ni wọn ṣẹṣẹ ri oku ọmọ yii lori akitan kan to wa leti odo nitosi ile wọn.
 
A tiẹ gbọ pe Baba Hassan, Ọgbẹni Tajudeen Adefuyi sọ fun ọmọ naa pe ko lọ maa ṣere ninu ile lasiko to fẹẹ jade lọ, ti wọn si l'ọmọ naa sare wọle, ṣugbọn ko pẹ to tun fi jade sita pada.
 
Aarin asiko yii la gbọ pe ọmọ naa d'awati.
 
Ninu ọrọ ti Tajudeen b'AWIKONKO sọ nipa iku ọmọ rẹ lo ti ni: “Igba ti mo n jade lọ ni mo sọ pe ko pada sile, o si sare wọnu ile lọ. Ko pẹ ni wọn wa sare pe mi nibi ti mo wa pe wọn ko ri Hassan, latigba naa la ti bere si i wa ni nnkan bi aago kan aabọ ọsan titi tile fi su..
 
"Aarọ ọjọ keji ni mo ṣẹṣẹ ri oku ọmọ mi lori akitan lẹgbẹ odo yii. Oro nla ni wọn da mi nitori pe arole ni ọmọ yii jẹ ninu awọn ọmọ mi. Oun nikan ni ọkunrin, ti inu si maa n dun ni gbogbo igba ti mo ba ti n ri i. Mo fẹ k'ijọba ran mi lọwọ lati mu awọn to pa mi l'ọmọ.
 
"Awọn ọlọpaa ti gbọ si ọrọ yii, ṣugbọn wọn ko yọju rara lati ṣe iwadii. Eyi ko bojumu to.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI