Ẹgbẹ́ Fijilante lorilẹ-ede Nàìjíríà, Vigilante Group of Nigeria (VGN) lábẹ́ ìṣàkóso Usman Jahun tí sọ pé ìgbésẹ̀ lọ́nà òfin tí bẹ̀rẹ̀ lórí gbogbo àwọn tó ń fi orúkọ ẹgbẹ́ náà lu àwọn aráàlú ni jìbìtì jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Ọlanrewaju Nureni Adedoyin lo sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó ń báwọn oniroyin sọ̀rọ̀ n'ilu Abẹ́òkúta laipẹ yìí to si ni ìwà táwọn ọbayejẹ náà ń hù tako òfin ètò ààbò orílẹ̀-èdè yìí.
Ọlanrewaju sọ pe gbogbo akitiyan lati maa wa alaafia f'awọn araalu ni ko tẹ awọn kan lọrun ti wọn fi n wa gbogbo ọna lati ba orukọ Fijilante jẹ loju awọn araalu, to si ni k'awọn eeyan dẹkun lati maa ri wọn gẹgẹ bi Fijilante, tori pe atijẹ ni wọn n wa kaakiri.
Laipẹ yii ni ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Umar Bakori gbe atẹjade kan sita f'awọn oniroyin wi pe idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun to sọ Usman Mohammed Jahun di adari ẹgbẹ Fijilante lorilẹ-ede Naijiria ko ni nnkankan ṣe pẹlu oun, to si ni gbogbo nnkan t'awọn eeyan ba fẹẹ ṣe nipa eto aabo fijilante ni ki wọn maa wa ba ẹgbẹ ti wọn.
Eyi ni agbẹnusọ naa, Ọgbẹni Ọlanrewaju Adedoyin tako wi pe ọkunrin kan ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ Fijilante tẹlẹ, to si lo ya awọn lẹnu bo ṣe dide lojiji lati maa pe ara rẹ ni adari ẹgbẹ naa lati maa fi ṣi awọn araalu lọkan.
Ninu ọrọ Adedoyin lo ti sọ pe "L'ọdun 2009, wọn dibo yọ Ali Ṣokoto to jẹ adari ẹgbẹ naa, wọn si yan Usman Jahun lati tẹsiwaju, ẹ ba mi beere pe nibo ni Bakori wa nigba yẹn. Ṣe inu ẹgbẹ VGN n lo wa nigba yẹn, ko si nibẹ rara.
"Nigba ti igbesẹ lati dẹkun Ali Ṣokoto lati maa pe ara rẹ ni adari ẹgbẹ naa bẹrẹ n'ile ẹjọ giga t'ilu Kaduna, nibo ni Bakori wa nigba naa. Nigba ti ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe Usman Jahun ni ko maa ṣakoso ẹgbẹ naa lọ, nibo ni Bakori wa, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ fijilante rara. Awọn alakoso ẹgbẹ VGN ni wọn yọ Ali Ṣokoto, ti wọn si fi Jahun rọpo ẹ.
"Ninu idajọ ti a gba nile ẹjọ kotẹmilọrun ni wọn ti darukọ Usman Jahun sibẹ pe oun gan an ni ko maa tẹsiwaju gẹgẹ bi adari ẹgbẹ VGN, ti ko si sẹni to le yii pada. Bawo lẹnikan yoo ṣe wa dide lati maa sọ pe oun loun ni ọfiisi to jẹ tẹnikan. Ẹ jẹ ka beere lọwọ ẹ pe talo yan an gẹgẹ bi adari.
"Pẹlu iwe ofin wa la fi n dari ṣakoso ẹgbẹ yii, awọn to n ṣakoso ẹgbẹ lapapọ ni wọn laṣẹ lati yan adari agba. Awọn wo wa ni alakoso ẹgbẹ yii ti wọn yan Bakori."
Nigba to n sọrọ lori bi Bakori ṣe sọ pe oun ni awọn iwe ti wọn fi f'orukọ ẹgbẹ VGN silẹ pẹlu ajọ Corporate Affairs Commission, CAC lọwọ, Adedoyin sọ pe irọ lo n pa, ko l'awọn iwe naa lọwọ, ati pe to ba tiẹ ni awọn iwe naa lọwọ, ṣe lo ji i, eyi to lo tako ofin orilẹ-ede yii.
"Nibo lo ti fẹẹ ri awọn iwe ẹri naa, awọn mẹsan-an ni wọn jẹ alakoso ti wọn f'orukọ ẹgbẹ VGN silẹ, orukọ Bakori ko si si nibikankan ninu wọn, bawo lo ṣe wa fẹẹ ni iwe ẹri lọwọ ti ki i ba ṣe pe o jiigbe.
"A ko gbọ pe wọn n wa awọn iwe ẹri naa, o si da mi loju wi pe ko si awọn iwe naa lọwọ ẹ. Ọkunrin naa kan n wa ọna lati ran ara rẹ lẹwọn ni."
Bakan naa nigba to n sọrọ lori ipo ti ẹgbẹ naa wa n'ipinlẹ Ogun, paapaa lori ọkunrin kan to loun ti gba ipo ACG bayii, iyẹn Ọgbẹni Oluṣọla Ṣodiyan, Ọlanrewaju sọ pe lara awọn kanda to n ba orukọ ẹgbẹ naa jẹ ni, ti igbesẹ si ti n lọ lori oun naa.
"Emi ko mọ ibi ti ọkunrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Oluṣọla Ṣodiyan ti gba ipo ACG to n pe ara rẹ bayii, nitori pe nigba ti wọn maa fun mi ni ipo agbẹnusọ n'ilu Abuja, mo mọ gbogbo awa ti a jọ gba ipo tuntun.
"Bi wọn ṣe gbe awọn kan leke naa ni wọn yi ipo awọn mi in pada. Ọjọgbọn Nelson Faṣina ti wọn jẹ ọjọgbọn nipa imọ ede Gẹẹsi ni fasiti Ibadan jẹ adari tẹlẹ, wọn si fun wọn ni ipo tuntun ti ACG, awọn tun ni agbẹnusọ tẹlẹ; Alaaji Saka lati Kwara naa gba ipo tuntun.
"Ṣodiyan yii ko si ninu ẹgbẹ fijilante ipinlẹ Ogun n'igba ti mo fi wa gẹgẹ bi adari n'ibẹ, awọn iwa to hu lo jẹ ka fun un n'iwe ẹsun lẹẹmẹta ọtọọtọ, iyẹn query, ti ko si dahun ẹ ko di pe o salọ.
"Lara awọn iwa to hu ta a fi fun n'iwe ẹsun ni pe o maa n sọ awọn ọrọ ti ko ri, iyẹn awọn ọrọ to le da wahala silẹ, o tun gbiyanju lati kẹyin awọn ọmọṣẹ si ọga, bẹẹ lo tun gbe mọto ẹgbẹ wa lati maa fi tọrọ owo lọwọ awọn oloṣelu, awọn nnkan wọnyi lo jẹ ka fun un niwe pe ko wa dahun awọn ẹsun naa, ṣugbọn ṣe lo salọ kaka ko dahun wọn.
"Awa ki i fi iṣẹ eto aabo tọrọ baara, bẹẹ la o ku fi i ṣe oṣelu, tori pe eto aabo araalu patapata la wa fun ki alaafia le tubọ maa jọba. Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ, igbesẹ ti n lọ lọna ofin lori gbogbo awọn to n ba orukọ égbẹ yii jẹ patapata, ti ẹ si maa gburo gbọ laipẹ.
"A ti fi ẹjọ wọn sun awọn ọlọpaa, ti wọn si ti pe wọn, ṣugbọn ti wọn ko lọ da awọn ọlọpaa lohun."
No comments:
Post a Comment