IWADII BẸRẸ LORI AWỌN TO PA GBAJUMỌ ỌBA L'AKURẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 27, 2020

IWADII BẸRẸ LORI AWỌN TO PA GBAJUMỌ ỌBA L'AKURẸ


Bi ẹ n ṣe ka iroyin yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lati ṣe iwadii awọn agbanipa ti wọn ṣeku pa Ọba Israel Adeusi, Olufọn tilu Ifọn nirọlẹ ana.
 
Opopona Benin si Ọwọ lọ si Akurẹ, iyẹn lagbegbe Elegbeka n'ijọba ibilẹ Ose.
 
A gbọ pe ilu Akurẹ ni Ọba Adeusi ti n bọ, to si n lọ silu Ifọn ko to di pe awọn agbanipa naa lọ dẹbuu ẹ lọna, ti wọn si dabọn bo mọto ẹ.
 
B'awọn agbanipa naa ṣe ṣiṣẹ wọn tan, la gbọ pe awọn to wa nitosi sare gbe e lọ si ọsibitu FMC to wa ni Ọwọ, ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI