KWARA BU ỌWỌ́ LU MÍLÍỌ̀NÙ MỌKANLELOGOJI LÁTI GBÓGUN TI ÀÌSAN IBÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 27, 2020

KWARA BU ỌWỌ́ LU MÍLÍỌ̀NÙ MỌKANLELOGOJI LÁTI GBÓGUN TI ÀÌSAN IBÀ


Owo ti ko di ni ni miliọnu mọkanlelogoji (41m) naira la gbọ pe ijọba ipinlẹ Kwara bu ọwọ lu lati fi gbogun ti aisan iba jakejado ipinlẹ naa fun ọdun 2020. 
 
Kọmiṣanna fun eto ilera ipinlẹ naa, Dọkita Raji Razaq lo sọrọ naa sita laipẹ yii lasiko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn ti wọn pe ni Long Lasting Campaign Coordinating Network Committee (LLCCN).
 
O ni ijọba ipinlẹ naa n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe alaafia j'ọba laaarin awọn araalu, ki wọn si wa ni ilera pipe.
 
Dọkita Raji wa gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ to fẹẹ fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lori eto yii, to si ni awọn naa yoo tubọ maa ran wọn lọwọ. 
 
Bakan naa ninu iroyin mi in la gbọ pe ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe awọn yoo lo gbogbo agbara wọn lati maa ṣagbatẹru awọn igbimọ to n ṣakoso ohun alumọọni ati eto ayika, iyẹn Mineral Resources and Environment Management Committee, MIRECO lati mu ki eto ọrọ aje tubọ maa dagba soke si i.
 
Kọmiṣanna fun eto iṣuna, Oyeyẹmi Ọlasumbọ lo sọrọ naa lasiko to n gba awọn igbimọ naa lalejo nilu Ilọrin, ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI