KO SẸNI TÓ NÁ OWÓ VGN LỌ́NÀ ÀÌTỌ́ - JAHUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

KO SẸNI TÓ NÁ OWÓ VGN LỌ́NÀ ÀÌTỌ́ - JAHUN


Oludari pátápátá fún ẹgbẹ́ eleto ààbò fijilante l'órílẹ̀-ède Nàìjíríà, ìyẹn Vigilante Group of Nigeria {VGN}, Ọmọwe Mohammed Usman Jahun tí sọ pé irọ́ tó jìnnà sí òtítọ́ ni pé àwọn kan na owó egbe naa ninakuna, àti pé àwọn arijẹnidimadaru lo wá nìdí ẹ.

Usman Jahun ló sọ̀rọ̀ náà n'ilu Abuja lásìkò to ń báwọn akọroyin sọ̀rọ̀, níbi tó ti sọ pé ṣe làwọn ń dá owó láti fi tukọ ẹgbẹ́ náà ni, kí í ṣe pé àwọn ń gba owó níbikíbi. 

O ni ọkùnrin kan tó pé ara rẹ ní Umar Abubakar Bakori tó ń gbé ìròyìn ẹlẹjẹ káàkiri wí pé àwọn kò lo owó ẹgbẹ́ náà dáadáa, tó sì ni igbesẹ òfin tí ń lọ lórí ẹ. 

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI