Ẹ FURA O! ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢÍ WÁ NÍTA Ò - ÌJỌBA KWARA PARIWO SÍTA FÁWỌN ARÁÀLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 29, 2020

Ẹ FURA O! ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢÍ WÁ NÍTA Ò - ÌJỌBA KWARA PARIWO SÍTA FÁWỌN ARÁÀLÚ


Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ àkóso Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí gba gbogbo àwọn aráàlú lamọran wí pé kí wọn dẹ́kun láti yé e tẹ òfin ajakalẹ àrùn Koronafairọọsi, ìyẹn Covid-19 lójú mọ́lẹ̀, nítorí pé ó ṣì wà níta rẹpẹtẹ. 

Lónìí ní Gómìnà AbdulRazaq sọ̀rọ̀ náà, tó sì ni bí ajakalẹ àrùn náà bá tún dìde bí í tí àkọ́kọ́ ó ṣeé ṣe kí agbára àwọn eleto ìlera má ká a mọ. 

Fún ìdí èyí, ó ní káwọn èèyàn gbìyànjú láti máa tẹle àwọn ìlànà àti òfin tó lè dẹ́kun àrùn náà fún àlàáfíà gbogbo èèyàn.

AWIKONKO gbọ pé àrùn náà tún ṣekú pá àwọn èèyàn kan lónìí n'ipinlẹ náà, tó sì mú káwọn tó ti kú pé ọgbọn báyìí. 

Nígbà tó ń gba ẹnu ìjọba ìpínlẹ̀ sọ̀rọ̀, agbẹnusọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣàkóso àrùn náà, Rafiu Ajakaye, ẹni tó tún jẹ́ akọ̀wé ìròyìn Gómìnà sọ pé pupọ àwọn aráàlú ni wọn ti pá àwọn ìlànà láti dẹ́kun àrùn náà tí. 

Ajakaye ni káwọn èèyàn dẹ́kun ipejọpọ rẹpẹtẹ láwùjọ, kí wọn máa lo aṣọ ìbòjú-bomú, kí wọn sì máa fọ ọwọ wọn déédéé. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI