KORONAFAIRỌỌSI: ORIIRE NLA TUN WỌ KWARA, WỌN GBA MILIỌNU MARUN-UN DỌLA OWO IRANWỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 17, 2020

KORONAFAIRỌỌSI: ORIIRE NLA TUN WỌ KWARA, WỌN GBA MILIỌNU MARUN-UN DỌLA OWO IRANWỌ

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu idunnu nla ni gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara jakejado agbaye wa bayii lori bi ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ṣe tun fi owo iranwọ lori ajakalẹ arun koronafairọọsi, iyẹn Covid-19 ta wọn lọrẹ.
 
Owo naa ti wọn ni miliọnu marun-un dọla, eyi to din diẹ ni biliọnu meji naira la gbọ pe ijọba apapọ fun wọn l'ọjọ Aje-Mọndee ana.
 
Ki i ṣe pe ijọba Kwara dee de gba owo yii, ṣugbọn lara awọn owo tíjọba fi kun eto iṣuna owo wọn lati fi ṣe iranlọwọ f'awọn ijọba ipinlẹ at'awọn araalu lo mu k'ijọba apapọ yọnda owo naa fun wọn.
 
Ijọba Kwara lo gbe iroyin yii sita nipa ti eto ti wọn fi n finu han awọn araalu, eyi ti wọn pe ni State Transparency, Accountability and Sustainability (SFTAS), paapaa lati le jẹ k'awọn eeyan maa mọ bi nnkan ṣe n lọ si.
 
Kọmiṣanna fun eto iṣuna ipinlẹ Kwara, Ọlasunmbọ Florence Oyeyẹmi ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn owo yii ni yoo jẹ ki ipinlẹ naa tete ṣe iranlọwọ to ba yẹ f'awọn ti ajakalẹ arun naa dori eto okoowo wọn kodo.
 
Ninu iroyin mi in to yatọ si eyi ni ijọba ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe Ọjọru-Wẹsidee ọla ni igbimọ ti yoo ri sọrọ awọn araalu t'awọn ọlọpaa ti fi iya aitọ jẹ yoo bẹrẹ ijokoo wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe ko din ni mejidinlogun ẹsun ọtọọtọ t'awọn araalu ti kọ ranṣẹ s'awọn igbimọ mọ lati fi takọ awọn iwa aibikita ọlọpaa s'awọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI