O PARI! ẸGBẸ ILẸ YORUBA DARU PATAPATA, NI WỌN BA YỌ BANJI AKINTOYE DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 17, 2020

O PARI! ẸGBẸ ILẸ YORUBA DARU PATAPATA, NI WỌN BA YỌ BANJI AKINTOYE DANU


Olufilọlẹ ẹgbẹ ọmọ Yoruba tuntun, Comrade Victor Taiwo ti ni awọn gbe ẹgbẹ Yoruba World Assembly silẹ lati wa ọna abayọ si aisi ifẹ ati ifimọsọkan laarin awọn ọmọ Yoruba.


Victor Taiwo to sọrọ nibi ifilọlẹ to waye ni ilu Ibadan naa ni ilẹ Yoruba nilo idagbasoke.

Ẹgbẹ naa ni ilọsiwaju ọmọ Yoruba ninu ọrọ aje, ihuwasi, eto ẹkọ ati ẹsin gbọdọ wa ni ifimọṣọkan fun ilọsiwaju.

Taiwo ni ẹgbẹ awọn Yoruba to ku ti kuna lati ṣe ohun to tọ, eleyii to jẹ ki ifaṣẹyin wa fun ilẹ Yoruba.

'' Ẹ wo bi eto aabo ṣe dẹnukọlẹ ni ilẹ Yoruba, ti ijinigbe n waye loore-koore lai ka awọn ẹmi ti awọn ajinigbe n pa ni ilẹ Yoruba''

''Lẹyin ti wo gbogbo iṣẹlẹ yii ni a ṣe apero awọn agbagba ilẹ Yoruba, ki a to da ẹgbẹ Yoruba World Assembly silẹ''

''Otitọ si ni pe imọ awọn ọmọ Yoruba ko ṣe ọkan ni gbogbo igba, nitori aigbọraẹniye to wọpọ laarin awọn agbaagba''

''A ko nifẹ si iru ẹgbẹ ti ina wọn n jo ajorẹyin mọ, nitori naa ni ẹgbẹ ti yoo mu ifimọsọkan ni okunkundun ṣe koko, o ṣe pataki.''

Lasiko ti ẹgbẹ tuntun naa n sọrọ lori ipo ti Ọjọgbọn Banji Akintoye wa gẹgẹ bi '' Adari ni ilẹ Yoruba, wọn ni Akintoye ti yọ ara rẹ kuro ninu ẹgbẹ ọmọ Yoruba nitori naa ki i se adari wọn mọ.

Yoruba World Assembly fikun pe Akintoye ti ja ọpọlọpọ ẹgbẹ to gbimọpọ yan an gẹgẹ bi adari, nitori naa kii ṣe adari wọn mọ.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, Ọjọgbọn Banji Akintoye ko tii fesi si igbesẹ ti awọn to fi ẹgbẹ yii lọọlẹ gbe.
 
Lati BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI