LẸYIN TI WỌN BORI IDIJE L'ABUJA, ADORABLE ANGELS S'ABẸWO SI GOMINA ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 19, 2020

LẸYIN TI WỌN BORI IDIJE L'ABUJA, ADORABLE ANGELS S'ABẸWO SI GOMINA ABDULRAZAQ

 
Ọjọru-Wẹsidee ana ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu aalafọwọgba l'obinrin n'ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara Adorable Angels gba aami ẹyẹ idijẹ bọọlu alafọwọ gba to waye n'ilu Abuja laipẹ yii ṣe abẹwo si Gomina AbdulRazaq lati fi awọn ẹbun ti wọn gba han an.
 
Ife ẹyẹ (Trophy) ati awọn ami ẹyẹ mi in ti ko din ni mejila ni wọn gba lẹyin idije naa to waye ni papa iṣere MKO Abiọla to wa nílu Abuja.
 
AWIKONKO gbọ pe lara awọn nnkan to jẹ ki lọ ki Gomina ni lati fi erongba wọn han nipa awọn nnkan ti wọn n dojukọ ati iranlọwọ ti wọn n fẹ.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe Gomina AbdulRazaq tiṣe abẹwo si wọn, to si gba wọn lamọran lati ni ọkan akikanju lati bori idije naa.
 
Ni bayii, Gomina AbdulRazaq ti ṣeleri iranlọwọ to ba yẹ f'awọn agbọọlu naa, ati pe oun yoo ji eto ere idaraya n'ipinlẹ naa pada si bo ṣe wa tẹlẹ.
 
Diẹ ree lara awọn fọto ti wọn ya:


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI