ỌPẸ O! AWỌN OLUGBE KWARA BỌ LỌWỌ AISAN IBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 19, 2020

ỌPẸ O! AWỌN OLUGBE KWARA BỌ LỌWỌ AISAN IBA


Ko din ni aawọn apẹfọn miliọnu meji aabọ din diẹ (2.3m) ti ijọba ipinlẹ Kwara fẹẹ pin fun gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara jakejado lojuna lati din aisan iba.
 
Lonii ni Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq fi eto pinpin aawọn apẹfọn lelẹ nilu Ilọrin, nibi to ti sọ pe eto ilera ati igbaye-gbadun araalu lo jẹ oun logun.
 
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni ida aadọta ailera awọn kaakiri ile iwosan eeyan lo jẹ pe nipa aisan iba lo ti wa, ati pe ai le ṣabojuto lọna to yẹ lo jẹ ki aisan naa maa gba ọna mi in yọ. 
 
 
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti ṣeleri pe gbogbo araalu patapata loun yoo ri daju pe wọn gba aawọn apẹfọn naa lati le gbogun ti ajaklẹ arun, ati pe awọn nnkan to ba yẹ n'ijọba yoo ṣe lati ri i pe awọn eeyan n wa ni ilera pipe ni gbogbo igba.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI