O MA ṢE O! GBAJUMỌ AṢỌLE LIVERPOOL TẸLẸ KU LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 16, 2020

O MA ṢE O! GBAJUMỌ AṢỌLE LIVERPOOL TẸLẸ KU LOJIJI


Inu ibanujẹ nla ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu nni, Liverpool wa bayii lori bi ẹni to n dile mu fun wọn tẹlẹ, Ray
Clemence ṣe jade laye lojiji lẹni ọdun mejilelaadọrin {72years}.
 
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lo kede iku Clemence lori ikanni ayelujara wọn l'ọjọ Aiku-Sannde ana, ti wọn si lo o ba wọn lọkan jẹ pupọ.
 
Ray Clemencela gbọ pe o jẹ ọkan lara awọn gbajumọ aṣọle agbaye, paapaa fun ikọ Liverpool. ọdun mẹtala gbako la gbọ pe Clemence fi di ile mu fun Liverpool to si kopa ni igba 665 lori papa.
 
Ọdun 1970 la gbọ pe Ray Clemence darapọ mọ Liverpool, ti wọn si ni manija wọn nigba naa, Bill Shankly lo bu ọwọ luu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI