O MA ṢE O! ỌJA IYAWO AJIMỌBI JONA N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 8, 2020

O MA ṢE O! ỌJA IYAWO AJIMỌBI JONA N'IBADAN


Ṣe lọrọ di olori di ori ẹ mu lọsan onii ti i ṣe Aiku-Sannde n'igba ti ina deede ṣẹyọ ni gbajumọ ọja igbalode kan, Grandex Supermarket to jẹ ti iyawo Gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Abiọla Ajimọbi, iyẹn Arabinrin Florence Ajimọbi.

Agbegbe Bodija to wa nilu Ibadan ni ọja naa wa, to si gbajumọ daadaa kaakiri igboro ilu Ibadan.

Bo tilẹ jẹ ko ti i sẹni to le f'idi nnkan to ṣokunfa ina naa lelẹ, ṣugbọn sibẹ, orin ọpẹ l'awọn eeyan n kọ nigba ti wọn sọ pe ko sẹni to ku, bẹẹ si ni ko sẹni to farapa ko to di pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana debẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI