ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN ẸIYẸ MEJE WỌ GAU N'IKORODU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN ẸIYẸ MEJE WỌ GAU N'IKORODU


Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ko din ni meje lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ lagbegbe Agura to wa nilu Ikorodu, ipinlẹ naa.
 
Ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ buruku wọn lọwọ la gbọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ wọn. AWIKONKO gbọ pe awọn eleto aabo ti wọn pe ni Agbẹkọya la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa lọọ koju, ti ọwọ palaba wọn si pada segi.
 
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi lo f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si darukọ awọn meje naa bi i: Abọlaji Adebayọ, ọmọ ọdun mọkanlelogun; Josiah Offem, ọmọ ọdun mẹtadinlogoji; Oluwapẹlumi Oyeyinka, ọmọ ọdun marundinlọgbọn; Lamidi Taofeeq, ọmọ ọdun mọkanlelogoji; Ahmed Shittu, ọmọ ọdun mejidinlaadọta; Rabiu Ganiyu, ọmọ ọdun marundinlọgbọn ati Zainab Nurudeen, ọmọ ogun ọdun.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe oriṣiriṣi ada pana ati ọbẹ, oogun abẹnugọngọ ati bọọsi alawọ ewe kan ti nọmba idanimọ ẹ jẹ LAGOS APP 600 XA ni wọn ri gba lọwọ wọn.
 
A gbọ pe kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe ki wọn ṣi ko wọn lọ si Panti lfun iwadii kikun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI