Ẹ WO OJU ỌLỌPAA TO MUTI YO NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 30, 2020

Ẹ WO OJU ỌLỌPAA TO MUTI YO NITA GBANGBA


Afaimọ ni ki wọn ma pada gba iṣẹ lọwọ ọlọpaa kan ti wọn loo muti yo nilu Abuja laipẹ yii, to si mu k'awọn eeyan maa fi ṣẹlẹya kaakiri igboro.
 
Ohun ti a gbọ ni pe fọnran ọlọpaa naa lo tan kaakiri ori ayelujara laipẹ yii, nibi ti ọlọpaa naa ta a ko mọ orukọ rẹ lasiko ta a kọ iroyin yii tan ti mu ọti yo bamu.
 
Bi fidio naa ṣe tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ la gbọ pe wọn ti ranṣẹ pe e lati wa a sọ tẹnu ẹ nipa idi to fi doju ti ileeṣẹ naa nita gbangba.
 
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, Yusuf Mariam fi sita lana ti i ṣe Sannde lo ti sọ pe ọkunrin naa ti wa lahamọ nibi to ti n sọ tẹnu ẹ, to si l'awọn yoo fi iya ofin to tọ jẹ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI