ẸGBẸ ASUU ṢALAYE NNKAN TI WỌN N FẸ FUN IJỌBA APAPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 22, 2020

ẸGBẸ ASUU ṢALAYE NNKAN TI WỌN N FẸ FUN IJỌBA APAPỌ


Apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti, iyẹn Academic Staff Union of Universities {ASUU} lorilẹ-ede Naijiria ti sọ pe bi ijọba apapọ ba fẹ k'awọn pada sẹnu iṣẹ laaarin ọsẹ kan, afi ki wọn fi ọwọ ti wọn fi n mu ileeṣẹ eto ọkọ ofurufu mu awọn naa.
 
O ni gbogbo bi wọn ṣe n lori ilọsiwaju ileeṣẹ ọkọ ofurufu, iyẹn Aviation Sector orilẹ-ede yii ni ki wọn bẹrẹ si i ṣe fun ẹka eto ẹkọ lai ṣe ojuṣaaju.
 
Alaga ẹgbẹ naa Ọmọwe Edor J. Edor ni fasiti t'ilu Calabar lo sọrọ yii jade wi pe awọn naa ṣetan lati pada sẹnu iṣẹ wọn, bi ijọba apapọ ba ti ṣetan lati ṣe awọn ojuṣe wọn to yẹ.
 
Ọmọwe Edor ni gbogbo ipa ati agbara ti ijọba n sa lori ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa ni ki wọn maa lo lẹka eto ẹkọ fun ilọsiwaju ati idagbasoke ẹka naa.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
“Bi ijọba ba le lo gbogbo agbara ti wọn n lo lati fi mu ilọsiwaju ba ileeṣẹ ọkọ ofurufu lori ẹka eto ẹkọ ni, awọn ileewe yoo pada laaarin asiko perete. Bi wọn ba lo awọn okun ati agbara wọn, eyi to n jẹ k'awọn ọmọ wọn maa wọ ọkọ ofurufu lọ kawe loke-okun, o daju pe laaarin ọsẹ kan, awọn ileewe lorilẹ-ede Naijiria yoo pada bẹrẹ iṣẹ."

Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ ijọba ana ati ijọba asiko yii wi pe wọn ko da si ọrọ eto ẹkọ rara, to si ni ṣe ni wọn pa a ti bi idọti ti ko kan wọn rara.

O l'awọn alẹnulọrọ laaarin ilu ni wọn ko bikita nipa eto ẹkọ mẹkunnu, to si ni b'awọn ọmọ ti wọn ba ti n kawe loke okun, eyi to ku kere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI