WỌN FOJU BABA ARUGBO BA ILE ẸJỌ LORI ỌMỌ ỌDUN MẸRINDINLOGUN TO FIPA BA LAṢEPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 10, 2020

WỌN FOJU BABA ARUGBO BA ILE ẸJỌ LORI ỌMỌ ỌDUN MẸRINDINLOGUN TO FIPA BA LAṢEPỌ


Baba arugbo ẹni ọdun mọkanlelaadọta lo ti f'oju ba ile ẹjọ majisireeti to wa nilu Kaduna, ipinlẹ Kaduna lori ẹsun wi pe o fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹrindinlogun.
 
Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa to kọja yii la gbọ pe baba arugbo naa, Joseph Alhassan fipa ja ibale ọmọ naa lagbegbe Shagari Lowcost Barnawa, ipinlẹ Kaduna.
 
Ẹsun ti wọn fi kan Alhassan la gbọ pe o tako ofin ifipabanilopọ ipinlẹ naa t'ọdun 2017, ti wọn si lo o ni ijiya nla ninu.
 
Onidajọ ile ẹjọ naa, Benjamin Hassan ko gba ẹbẹ baba naa, to si ni ki awọn ọlọpaa ṣi lọ fi pamọ s'ọgba wọn digba ti idajọ mi in yoo fi waye lọjọ karundinlọgbọn oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI