O PARI! NITORI IWỌDE 'ENDSARS', WỌN GBE PASITỌ ADEYẸMI, 2FACE, DAVIDO, KANU AT'AWỌN MI-IN LỌ SILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 10, 2020

O PARI! NITORI IWỌDE 'ENDSARS', WỌN GBE PASITỌ ADEYẸMI, 2FACE, DAVIDO, KANU AT'AWỌN MI-IN LỌ SILE ẸJỌ


Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Kenechukwu Okeke lo ti gbe awọn ti ko din ni aadọta lọ sile ẹjọ lori iwọde ifẹhonu han alalaafia ifọpin s'awọn ọlọpaa SARS, eyi ti wọn pe ni #ENDSARS.
 
Okeke ti wọn loo jẹ gbajugbaja nidi ka maa sọrọ bi nnkan ṣe n lọ laaarin ilu, iyẹn Activist lo fẹsun kan awọn aadọta naa wi pe wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe ba dukia oun jẹ lori iwọde ifẹhonu han #ENDSARS naa to waye l'oṣu to kọja, to si ni wọn gbọdọ foju winna ofin orilẹ-ede yii.
 
Lara awọn to gbe lọ si kọọtu ni: Damini Ogulu, iyẹn Burna Boy; David Adeleke ti wọn n pe ni Davido; Fọlarin Falana ti i ṣe Falz; Debọ Adebayọ, iyẹn Mr Macaroni; Maryam Akpaokagi ti wọn n pe ni Taoma; Peter ati Paul Okoye, Innocent Idibia, iyẹn Tuface, Bankọle Wellington, iyẹn Banky W; Tiwa Savage, Michael Ajereh ti wọn n pe ni Don Jazzy ati Yẹmi Alade.
 
Awọn mi in ni Pasitọ ṣọọṣi Daystar Christian Centre, Pasitọ Sam Adeyẹmi; Aisha Yesufu; Kanu Nwankwo; Ọmọwe Joe Abah; Kiki Mordi; Yul Edochie; Uche Jombo at'awọn mi in.
 
Okeke ninu iwe ẹsun to fi kan awọn eeyan naa lo ti ni ipa ti wọn ko lasiko iwọde ifẹhonu han naa ko kere rara, eyi to loo jẹ ko di nnkan ti wọn n ba dukia jẹ kaakiri.
 
Ọkunrin naa ni ori ikanni ayelujara ti Twitter l'awọn toun fẹsun kan naa n lo lati fi da wahala silẹ, to si ni ẹsun toun fi kan wọn lọ ni ibamu pẹlu iwe ofin orilẹ-ede yii t'ọdun 2004, iyẹn Section 97(2) ti Penal Code Act, C53 Laws of the Federation of Nigeria, 2004.

O ni ṣe lawọn eeyan naa f'awọn tọọgi laaye lati ba dukia oun jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI