WỌN JU MUTIU SẸWỌN ỌDUN MẸRINLA L'ABẸOKUTA, FUFU LO FI TAN ỌMỌ NAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 14, 2020

WỌN JU MUTIU SẸWỌN ỌDUN MẸRINLA L'ABẸOKUTA, FUFU LO FI TAN ỌMỌ NAA

Ọdun mẹrinla gbako ni baale ile ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan, Mutiu Ajibọla yoo lo lọgba ẹwọn lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
 
Ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mọkanla la gbọ pe Mutiu fipa ja ibale rẹ loju ọna Ọfada, to wa ni abule Ṣomoke, Owode-Ẹgba n'ijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode, ipinlẹ Ogun lọjọ  kọkanla oṣu kejila ọdun 2018.
 
AWIKONKO gbọ pe ọmọ naa ti mama rẹ gbe Fufu le lori lati kiri lọ ni Mutiu pe pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun fẹ ba a ra ọja, ti wọn si ni ṣe lo tan ọmọdebinrin yii wọnu ile, to si fipa ja ibale ẹ.
 
B'ọmọ naa ṣe dele lo ti sọ f'awọn obi ẹ, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ, ko to di pe wọn fóju ẹ ba ile ẹjọ. A gbọ pe Mutiu ti jẹwọ pe loootọ  ni fun adajọ, to si n bẹbẹ fun idariji.
 
Ṣugbọn nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu to jẹ adajọ agba nípinlẹ Ogun paṣẹ pe ki Mutiu lọọ fi ọdun mẹrinla gbako kẹkọọ siwaju si i nipa igbesi aye, ati pe ko lo anfaani naa lati yi iwa rẹ pada si rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI