ADIGUNJALE KỌJÚ ÌJÀ SÍ FIJILANTE L'ỌSIBITU, LÓ BÁ PÀDÉ IKÚ ÒJIJÌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 6, 2020

ADIGUNJALE KỌJÚ ÌJÀ SÍ FIJILANTE L'ỌSIBITU, LÓ BÁ PÀDÉ IKÚ ÒJIJÌ


Bí wọn ba n ra koro de ọrun ni, òkú tí ẹ ń wo yìí yóò ti wá níwájú bàbá Gọọdu níbi tí yóò ti máa kawọ pọyin rojọ ohun to wá ṣe láyé. 

Ọjọ Satide tí í ṣe Abamẹta àná là gbọ àwọn adigunjale yawọ ọsibitu lagbegbe Ubiaja to wá nijọba ìbílẹ̀ Esan South, ipinlẹ Ẹdo, tí wọn sì gba dúkìá lọ́wọ́ àwọn èèyàn nibẹ. 


Lára àwọn tó wà nibẹ là gbọ pé wọn ranṣẹ sáwọn ọmọ ẹgbẹ́ Fijilante láti wá a rán wọn lọ́wọ́, tí wọn ní wón kó fi ọ̀rọ̀ náà falẹ rárá. 

A gbọ pé bí àwọn Fijilante yìí ṣe debẹ, táwọn adigunjale náà tí kofiri wọn ní wón ti koju ìbọn sì wọn. 


Ṣe ni àkàrà wọn tú sepo nígbà táwọn Fijilante náà gbà ọ̀nà ẹburu yọ sí wọn, tí wọn sì rí gbogbo wọn kò. Ọkàn lára wọn tí wọn lòun lagidi là gbọ pé ìbọn padà bá, tó sì gbabẹ sọdá sọrun alakeji. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI