ẸLẸ́WỌ̀N MẸTA TO SALỌ L'ẸDO TÚN PADÀ WỌ GAU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 6, 2020

ẸLẸ́WỌ̀N MẸTA TO SALỌ L'ẸDO TÚN PADÀ WỌ GAU


Mẹta ninu awọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọn na pápá bora lásìkò iwọde ipolongo #Endsars lọjọsi n'ilu Benin, ipinlẹ Ẹdo lọwọ ọlọpaa tún ti padà tẹ báyìí. 

Osamuyi Omoregbe, Raymond Aimua àti Omon Ayọ lórúkọ àwọn mẹtẹẹta tí a gbọ pé wọn wá lára àwọn mẹrinlelọgbọn tí ileeṣẹ ọlọpaa fojú wọn hàn fáwọn oniroyin. 

A gbọ pé ẹ̀sun idigunjale niwon tún pads fi kan wọn nígbà tọwọ palaba wọn segi. 

Johnson Kokumọ to jẹ́ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ẹdo lo fìdí ọrọ náà múlẹ̀ wí pé ibi tí wọn tí ń jalè lọwọ tí tẹ wọn. 

O ni awon yoo fojú àwọn mẹtẹẹta náà bá ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sun wí pé wọn salọ lọgba ẹwọn tí wọn wá àti ẹ̀sun titun tí wọn tun ṣẹ.

A gbọ ọkọ̀ akero làwọn ọ̀daràn náà fi ń ṣiṣẹ láti máa fi lu àwọn aráàlú ni jìbìtì. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI