AWỌN ANGẸLI TO N ṢỌ MI KO NI I DARIJI MI BI MO BA PARI AAWỌ PẸLU ỌBASANJỌ - GANI ADAMS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 8, 2020

AWỌN ANGẸLI TO N ṢỌ MI KO NI I DARIJI MI BI MO BA PARI AAWỌ PẸLU ỌBASANJỌ - GANI ADAMS


Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Iba Gani Adams ti sọ pe ko si nnkan naa to fẹ pa oun ati Aarẹ ana lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ pọ mọ lailaie, to si ni awọn angẹli to n ṣọ oun loju mejeeji ko ni i dariji oun bóun ba gbiyanju lati yanju aawọ to wa laaarin wọn.
 
Lonii ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun-Tuside ni Aarẹ Ọna Kakanfo sọrọ naa nile ẹ to wa ni Ọmọle nilu Eko, nibi ipade to ṣe pẹlu awọn akọroyin.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Iba Gani Adams pade nile Oloye Ayọ Adebanjọ, eyi t'awọn oniroyin kan gbe jade wi pe ija to wa laaarin awọn mejeeji ni wọn lọ yanju.

Ṣugbọn ni kete ti iroyin naa jade sita ni Oloye Ọbasanjọ ti sọ pe oun ko pari ija kankan pẹlu Gani Adams tori pe iwa to n hu nigba kan ri ko ba t'oun mu, too si l'oun ko ti i fi aaye silẹ fun Aarẹ Adams lati wa a ki oun nile.
 
Iba Gani Adams ninu ọrọ rẹ sọ pe oun ko ri idi kan ni patọ lati pari aawọ to wa laaarin oun ati Oloye Ọbasanjọ, ati pe oun ko le ba ẹni to n fi oju eeyan buruku wo oun ni gbogbo igba lajọṣepọ.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Mi o mọ nnkan ti Baba Ọbasanjọ n sọ nipa igbe aye mi. Mo gba loootọ wi pe a ko jọ ni iwa kan naa nitori pe ki i ṣe ẹni to nifẹ ilọsiwaju (progressive). Ọbasanjọ ko le fẹran ọmọ Naijiria to ba n tẹsiwaju.
 
"Mi o ti f'igba kan ni i lero wi pe ma a lọ ki Ọbasanjọ nile ẹ gẹgẹ bo ṣe sọ. Mi o kọkọ fẹ lọ sibi ipade naa nigba ti Oloye Ayọ Adebanjọ sọ fun mi. Ṣugbọn mo ni lati lọ nitori pe Oloye Adebanjọ wa lara awọn agba Yoruba ti mo maa n bọwọ fun gidi.

“Ọbasanjọ sọ  pe ẹni to ba fẹẹ ni ipade alaafia pẹlu oun ni lati wa ba oun nile ẹ to wa niluu Abẹokuta. Mi o nilo lati yanju aawọ kankan tabi ipade alaafia kankan pẹlu ẹ. Iyẹn ti di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ. Mi o tiẹ le lọ sile ẹ ni.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI