MI O LẸ ṢAI DUPẸ OOOOOOOOOOOOOOOOOOOO - GOMINA ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 8, 2020

MI O LẸ ṢAI DUPẸ OOOOOOOOOOOOOOOOOOOO - GOMINA ABDULRAZAQ


Wọn ni inu didun lo n mu koriya wa, ati pe yin-ni-yin-ni, keeyan le ṣe mi in ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq fi ọrọ awọọdu nla kan to ṣẹṣẹ gba laipẹ yii ṣe.
 
Aami ẹyẹ, iyẹn awọọdu gomina to ṣe daadaa julọ lorilẹ-ede Naijiria l'ọdun 2020 ni ileeṣẹ iwe iroyin LEADERSHIP fi ta Gomina Abdulrazaq lọrẹ, ti wọn si ni ki i ṣe ojuṣaaju ni wọn fun un laami ẹyẹ naa.
 
Ko sẹni to de ipinlẹ Kwara tẹlẹ, ati lasiko yii, ti ko ni i ri awọn iyatọ ati ipa rere ti Gomina naa ti ko, paapaa n'ipa awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to ṣe kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ Kwara, lai ya ibikibi silẹ.
 
Nigba to n fi imọriri rẹ han, Gomina AbdulRazaq sọ pe dandan ni koun dupẹ lorukọ oun ati awọn alabaṣiṣẹ pọ oun lọwọ ileeṣẹ iwe iroyin LEADERSHIP fun awọọdu  gomina to ṣe daadaa julọ l'ọdun 2020.
 
O ni awọọdu naa ṣe koko, to si ṣe pataki pupọ s'oun ati awọn alabaṣiṣẹ pọ oun patapata, leyi to ti yoo tun jẹ k'awọn tẹra mọ iṣẹ lati ṣe ju ti atẹyinwa lọ. Bẹẹ lo sọ pe o tun jẹ koun mọ pe awọn eeyan n wo awọn kaakiri agbaye nipa awọn iṣẹ t'awọn n ṣi n'ipinlẹ naa, eyi ti ko han s'awọn, to si ni ọpẹ nla ni fun Ọlọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI