DAVID LU IYA ỌMỌ RẸ PA L'ỌGANJỌ ORU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 8, 2020

DAVID LU IYA ỌMỌ RẸ PA L'ỌGANJỌ ORU


Bo tilẹ jẹ pe titi d'asiko ta a kọ iroyin yii tan la ko ti i mọ nnkan ti gendekunrin ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Promise Oliver David fi lu iya-ọmọ rẹ, Esther Pascal pa loru ọjọ Aiku ti i ṣe Sande ijẹta, sibẹ iyalẹnu n'iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ fun pupọ awọn to gbọ.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni nnkan bi aago mọkanla aabọ ni wahala nla bẹrẹ laaarin awọn mejeeji, iyẹn lasiko t'awọn eeyan ti n sun, nibẹ si ni Esther, ọmọ ọdun mejidinlogun ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
 
A gbọ pe ọmọdebinrin, ọmọ ọdun meji ni Esther bi fun David, ti wọn si ni ọpọ igba ni ija maa n waye laaarin wọn ninu ile, koda ti wọn l'awọn araale gan an ti ri ọrọ wọn gẹgẹ awada.
 
Lasiko ti wọn n fa wahala yii la gbọ pe awọn ti wọn jọ n gbe inu ile kan naa sare jade, nigba ti wọn ni Esther pariwo sita, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, Davidi ti tilẹkun lẹyin.

Pẹlu agidi la gbọ pe awọn araale naa fi ja ilẹkun wọle, ti wọn si ba oku Esther nilẹ. Wọn tiẹ gbiyanju lati rọ omi le obinrin naa lori boya yoo ji pada saye, ṣugbọn ti wọn ni ẹpa ko boro mọ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Loju ẹsẹ ni wọn ti sare ranṣẹ s'awọn ọlọpaa, iyẹn ni nnkan bi aago mejila oru, ti wọn si l'awọn ọlọpaa lo pada palẹmọ oku Esther kuro nilẹ, ti wọn si gbe David lọ si teṣan wọn.
 
Ilu Yenagua n'ipinlẹ Bayelsa n'iṣẹlẹ naa ti waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI