ORIIRE NLA DE! ẸGBẸ OṢELU APC ṢE OFIN TUNTUN F'AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 8, 2020

ORIIRE NLA DE! ẸGBẸ OṢELU APC ṢE OFIN TUNTUN F'AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ TUNTUN


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti sọ pe aaye ti ṣi silẹ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun lati jade du ipo labẹle yoowu ti wọn ba fẹ du ninu ipo oṣelu orilẹ-ede yii.
 
Igbimọ alakooso apapọ, iyẹn National Executive Committee ẹgbẹ naa lo sọ eyi di mimọ lonii ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee wi pe awọn ti gboju fo ọdun meji to wa ninu iwe ofin ẹgbẹ wi pe ọdun meji gbako ni ọmọ ẹgbẹ tuntun yoo lo ko to le jade du ipo labẹ asia ẹgbẹ naa.

Ipade naa ti Aarẹ Muhammadu Buhari dari ẹ la gbọ pe gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ ni wọn wa nibẹ, to fi mọ awọn gomina. Nibẹ si ni wọn ti sọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP wi pe ki wọn yee fi ẹnu tẹmbẹlu ijọba wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI