#ENDSARS! GOMINA ABDULRAZAQ MU ILERI ṢẸ F'AWỌN ARAALU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 18, 2020

#ENDSARS! GOMINA ABDULRAZAQ MU ILERI ṢẸ F'AWỌN ARAALU


Ko din ni mejidinlaadọta awọn to ni ileeṣẹ kereje ai nla ti wọn gba iwe sọwedowo lọwọ ijọba ipinlẹ Kwara, gẹgẹ owo iranwọ fun idagbasoke okoowo wọn.
 
Awọn ileeṣẹ ti wọn padanu dukia wọn lasiko iwọde ifẹhonu han ENDSARS to waye l'oṣu kẹwaa ọdun yii l'awọn eeyan naa.
 
Ohun ta a gbọ ni pe miliọnu to din diẹ ni igba, iyẹn N180,775,000 naira ni ijọba pin f'awọn onileeṣẹ naa lati fi bẹrẹ lakọtun.
 
Lẹyin rogbodiyan ati wahala naa ni ijọba gbe igbimọ dide lati ṣe iwadii awọn ileeṣẹ ti wọn padanu dukia at'awọn ọja wọn, ti wọn si ṣe akọsilẹ gbogbo wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI