KỌMIṢANNA ỌLỌPAA KU LOJIJI, WỌN NI KORONA LO PA A - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 18, 2020

KỌMIṢANNA ỌLỌPAA KU LOJIJI, WỌN NI KORONA LO PA A


Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Cross River, Abdulkadir Jimoh la gbọ pe o ti jade laye lonii.
 
Aarọ onii ti i ṣe Fraide la gbọ pe ọkunrin naa ku si ọsibitu awọn olukọni tilu Calabar lẹyin ti wọn lo o ko ajakalẹ arun koronafairọọsi ti wọn tun n pe ni Covid-19.
 
Ọga agba ọsibitu naa, Ọjọgbọn Ikpeme Ikpeme lo f'idi iroyin iku Jimọh lelẹ f'awọn oniroyin.
 
AWIKONKO gbọ pe onii na ni wọn sare gbe Jimọh digbadigba lọ si ọsibitu naa lẹyin ti wọn ni aisan kan deede kọluu, ṣugbọn to pada dakẹ lẹnu ọna abawọle ọsibitu naa.
 
Ohun ta a gbọ ni pe oṣu marun-un pere ni Jimọh ṣi lo gẹgẹ bi kọmiṣanna n'ipinlẹ naa ko to jade laye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI