ETO IṢUNA IPINLẸ OGUN JA WALẸ F'ỌDUN 2021 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 3, 2020

ETO IṢUNA IPINLẸ OGUN JA WALẸ F'ỌDUN 2021


L'Ọjọru ti i ṣe Wẹsidee ana ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun gbe eto iṣuna ọdun 2021 to n bọ lọ siwaju awọn aṣofin ipinlẹ Ogun lati bu ọwọ lu.
 
Eto iṣuna ọdun 2021 naa la gbọ pe ọọdunrun biliọnu le diẹ, iyẹn N339b naira ijọba fẹẹ na bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu kinni titi de ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun naa.
 
L'ọdun to kọja, iyẹn ọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2019 ni Gomina Abiọdun gbe aba eto iṣuna f'ọdun 2020 to ṣẹṣẹ n pari lọ yii lọ sile igbimọ aṣofin kan naa lati bu ọwọ lu. N449.97 biliọnu naira lowo t'ijọba na l'ọdun fun awọn iṣẹ idagbasoke ni gbogbo ẹka.
 
N'igba to n sọrọ n'ibi aba eto iṣuna naa lana an, Gomina Abiọdun sọ pe biliọnu mọkanlelọgọta (N61b) naira ni awọn akanṣẹ iṣẹ idagbasoke yoo gba, ti eto ẹkọ yoo si gba biliọnu mejidinlọgọta (N58b), ati pe irolagbara awọn ọdọ yoo gba biliọnu mẹfa.
 
O tẹsiwaju pe Eto agbẹ yoo gba to biliọnu mẹẹdogun (N15b) naira, ti igbe aye awọn araalu naa yoo si gba biliọnu mẹtalelaadọrun-un (N93b) naira.
 
Siwaju si i ni Gomina Abiọdun tun jẹ ko di mimọ pe awọn akanṣẹ iṣẹ to n lọ lọwọ tẹlẹ ni yoo gba ju ninu aba eto iṣuna naa, ki iṣẹ naa le tete kẹsẹ jare.
 
Ninu ọrọ tirẹ, abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa, Ọnọrebu Ọlakunle Oluọmọ sọ pe awọn kọmiṣanna at'awọn adari lẹka eto ijọba ni wọn ṣetan lati f'idi eto i'ṣuna naa mulẹ lati ṣalaye bi wọn ṣe fẹẹ na awọn owo naa f'awọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI