OWO ARUGBO! Ẹ GBỌ OHUN T'AWỌN ARUGBO SỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 2, 2020

OWO ARUGBO! Ẹ GBỌ OHUN T'AWỌN ARUGBO SỌ


Bi wọn ba gun ẹṣin ninu gbogbo awọn arugbo patapata n'ipinlẹ Kwara lasiko yii, wọn ko ni i kọsẹ rara nitori pe inu idunnu ati ayọ nla ni gbogbo wọn wa patapata.
 
Gbogbo awọn arugbo at'awọn to ku diẹ kaato fun la gbọ pe ijọba ipinlẹ naa n fun ni owo iranwọ ninu eto ti wọn pe ni Owo Arugbo.

Ki i ṣe akọkọ ree t'awọn arugbo yoo maa gba owo yii, awọn arugbo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa ni wọn ti jẹ anfaani owo naa ni nnkan bi oṣu mẹrin sẹyin ninu ipele akọkọ.

Ipele keji to n lọ lọwọ yii, eyi to bẹrẹ lana ni awọn ẹgbẹrun mẹwaa mi in naa tun ti n jẹ anfaani naa.

Diẹ ree lara ohun t'awọn to gba owo naa sọ:
 
Mayaki Gudugi ni wọọdu kẹrin to wa ni Patigi "Inu mi dun gidi bi mo ṣe gba owo naa. Mo dupẹ lọwọ ijọba, paapaa Gomina AbdulRaazaq fun iranlọwọ nla yii."
 
Aishatu Madu ni wọọdu kẹta ni Patigi "Owo yii yoo tun mu ki nnkan rọrun fun mi, yoo kun owo ounjẹ emi ati mọlẹbi mi. Akoko ree ninu itan ipinlẹ Kwara, gbogbo awa ti a gba owo yii la ko ni i gba ijọba yii titi lai."




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI