GBOGBO AGBÈGBÈ ÀTI ÌGBÈRÍKO ÌPÍNLẸ̀ KWARA LA FẸẸ MÚ ÌDÀGBÀSÓKÈ BÁ - GÓMÌNÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 15, 2020

GBOGBO AGBÈGBÈ ÀTI ÌGBÈRÍKO ÌPÍNLẸ̀ KWARA LA FẸẸ MÚ ÌDÀGBÀSÓKÈ BÁ - GÓMÌNÀ


Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí sọ pé gbogbo àgbègbè àti ìgbèríko pátápátá tó wà ní ìpínlẹ̀ náà làwọn ṣetan láti mú ìdàgbàsókè bá, fún igbayegbadun àwọn aráàlú. 

Ọjọ́ Àìkú tí í ṣe Sannde tó kọjá yìí ni Gomina AbdulRazaq tún sọ̀rọ̀ náà síta láti ẹnu akọ̀wé ìròyìn ẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye níbi eto kan tí ẹgbẹ́ Countryside Emerging Leaders Fellowship (CELF) ṣe agbatẹru ẹ. 

Nibẹ ni Gomina tún ti fìdí rẹ múlẹ̀ pé kò sí àgbègbè tàbí ìgbèríko náà táwọn yóò yà silẹ fún eto ìdàgbàsókè, tàbí tí wọn yóò fi ẹtọ rẹ dùn ún, torí pé ìjọba aráàlú lòun ń ṣe. 
 
Ó tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé ààyè silẹ láti jẹ ki awon tó ní ẹ̀bùn dìde láti lo ẹ̀bun wọn, tó sì gbé oriyin fún ẹgbẹ́ náà lórí àfojúsùn wọn láti mú ìdàgbàsókè báwọn ògo wẹẹrẹ láwùjọ. 
 

Nibẹ náà ni Gomina tí ṣe ìlérí wí pé òun yóò fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ni mílíọ̀nù kan náírà láti ra fóònù tí yóò jẹ ki wọn le maa fi kan sì ara wọn nirọrun. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI