NNKAN DÉ! AJAKALẸ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI TÚN WỌ KWARA LẸẸKEJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 15, 2020

NNKAN DÉ! AJAKALẸ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI TÚN WỌ KWARA LẸẸKEJI


Ìgbìmọ̀ oludamọran eto ìlera, ìyẹn Kwara Medical Advisory Sub-Committee lórí ajakalẹ àrùn COVID-19 tí kéde síta wí pé ajakalẹ àrùn náà tún ti wà níta. 

Nínú atẹjade tí igbimọ náà fi síta laipẹ yìí, èyí tí Dọkita Fẹmi Ọladiji bù ọwọ lù lo tí sọ pé a káwọn aráàlú kíyèsí-ará lórí àrùn náà, kò má bàa tún fà konilegbele.

O ni ṣe làwọn èèyàn ro pe ajakalẹ àrùn náà tí ń kasẹ nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ lai mọ pe ṣe ló fara pamọ, àti pé àrùn náà tún ti ń padà báyìí bí àwọn ìpínlẹ̀ tó kú lórílẹ̀ èdè yìí. 

Ó ní afi káwọn èèyàn fi ara wọn silẹ báyìí fún àyẹ̀wò láti lè tètè dẹ́kun àrùn náà, tó sì ni ojú yẹpẹrẹ táwọn aráàlú fi ń wo àrùn náà lo jẹ́ kó tún dìde. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI