IJỌBA KWARA BANUJẸ LORI IKU OLUDASILẸ IWE IROYIN LEADERSHIP ATI QADI IMAAMU-FULANI TẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 13, 2020

IJỌBA KWARA BANUJẸ LORI IKU OLUDASILẸ IWE IROYIN LEADERSHIP ATI QADI IMAAMU-FULANI TẸLẸ


Wẹrẹ bayii ni iroyin iku oludasilẹ iwe iroyin oloyinbo nni, LEADERSHIP, Oloogbẹ Sam Nda-Isaiah ati Grand Qadi ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun Sahriah t'ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Onidajọ
Abdulkadir Imam-Fulani wọle, to si ba pupọ awọn eeyan lọkan jẹ gidi.

Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe ojiji ni iku Sam Nda-Isaiah b awọn to jẹ ibaujẹ nla fun wọn, to si loun ba gbogbo oniroyin kaakiri orilẹ-ede yii kẹdun
 
AbdulRazaq l'awọn ko le ṣai gbagbe ọkunrin naa ti awọn ipa to ti ko ninu idagbasoke orilẹ-ede yii ko ṣee gbagbe, paapaa lagboole akọroyin, to si ni ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
 
Bakan naa nigba to n sọrọ lori iku Abdulkadir Imam-Fulani, Gomina AbdulRazaq ni amofin toootọ ti ki i ṣe ojusaaju rara ni Oloogbe naa nigba aye ẹ, to si lo báwọn lọkan jẹ gidi nigba ti rioyin naa tẹ wọn lọwọ, ṣugbọn ti ko sohun ti wọn le ṣe lati da ẹmi rẹ duro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI