OPIN AYE, ỌMỌ ỌDUN MẸRINLA F'OJU BA ILE-ẸJỌ LORI ẸSUN IFIPABANILOPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 12, 2020

OPIN AYE, ỌMỌ ỌDUN MẸRINLA F'OJU BA ILE-ẸJỌ LORI ẸSUN IFIPABANILOPỌ


L'ọjọ Ẹti ti i ṣe Fraide ana ni wọn fi oju ọmọ ọdun mẹrinla kan, Abdullahi Sherif ba ile-ẹjọ mọlẹbi (Family Court) lori ẹsun ifipanilopọ ti wọn fi kan an.
 
Ọmọbinrin kekere kan la gbọ pe Sherif fipa ba lopọ lagbegbe Owu-Isin laipẹ yii, ti aṣiri ẹ si tu sita 
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni ọmọdebinrin naa n yagbẹ lọwọ ninu igbo ki Sherif to yo si i lati ẹyin, to si ṣe bẹẹ ko ibasun fun un karakara.
 
Agbẹjọro ọlọpaa, Adigun Adisa n'igba to n sọrọ niwaju adajọ nipa ẹsun to fi kan Sherif sọ pe ọsibitu Model Primary Health Care to wa ni Owu l'awọn ọlọpaa ti lọ ṣayewọ f'ọmọ naa, nibẹ si ni wọn ti f'idi rẹ mulẹ pe Sherif lo gba ibale ọmọdebirin ti a n sọ yii.
 
Adisa bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn ṣi fi Sherif sahamọ d'igba ti ẹjọ naa yoo fi pari, paapaa nigba táwọn iwadii mi in tun ṣi n lọ lọwọ.
 
Onidajọ Shade Lawal ninu ọrọ rẹ sọ pe ki wọn ṣi lọ fi Sherif pamọ sahamọ to wa ni Oke-Kura, Ilọrin, ki wọn si muu pada wa lọjọ kẹrindinlogun oṣu yii lati tẹsiwaju ẹjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI