IJỌBA KWARA SỌRỌ LORI AWỌN ATUNKỌ ILEEWE TO N LỌ LỌWỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 12, 2020

IJỌBA KWARA SỌRỌ LORI AWỌN ATUNKỌ ILEEWE TO N LỌ LỌWỌ


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe awọn ko ti i pari atunkọ awọn ile-ẹkọ to n lọ lọwọ kaakiri ipinlẹ naa, ti wọn si ṣalaye awọn nnkan to n da iṣẹ duro.
 
Laipẹ yii ni wọn ni ọkunrin kan Dare Akọgun gbe iroyin kan jade lori redio Sobi, iyẹn latari awọn iwadii to ṣe nipa awọn atunkọ naa, nibi to ti sọ pe gbogbo awọn akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ lo ti dawọ duro.
 
Ijọba ipinlẹ naa ti wa sọ pe ọrọ ko ri bi ọkunrin naa ṣe sọ ọ kalẹ f'awọn araalu.

N'igba ti wọn n ṣalaye awọn koko pataki to fa idaduro, ijọba Kwara ni ko ti i si eyi to ṣi pari ninu awọn ile-ẹkọ ti ọkunrin naa sọ, nitori pe awọn da awọn iṣẹ naa duro lati le mọ pe loootọ ni owo tíjọba gbe kalẹ fun awọn atunkọ naa ni wọn lo bo ṣe yẹ.

O ni o ti ya ju lati maa sọ pe ijọba ti pari awọn atunkọ naa pẹlu ipele t'awọn ti iṣẹ de duro. Wọn ni ijọba ri awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan to n ṣẹlẹ lori b'awọn agbaṣẹṣe ṣe n ṣiṣẹ yii, ti wọn si fẹẹ mọ idi to fi ri bẹẹ.

Eyi lo fa ti wọn fi gbe kọmiṣanna fun eto iṣuna dide lati tọpinpin bi awọn agbaṣẹṣe naa ṣe n na owo iṣẹ ti wọn gba lọwọ ijọba
 
Wọn jẹ ko ye awọn eeyan pe awọn fẹẹ jẹ k'awọn araalu mọ pe awọn ko lẹbọ-lẹru lo jẹ k'awọn fẹẹ tọpinpin bi nnkan ṣe n lọ. Bẹẹ ni wọn darukọ awọn ile-ẹkọ mẹjọ ti atunṣẹ ti n lọ lọwọ nilu Ọffa
 
Iyẹru Grammar School; CSS, Offa; GDSS, Offa; GSS Offa;  Nawairudeen Grammar School, Offa; Offa ACC, Offa; Mọremi High School, Offa; ati Okin High School, Offa.
 
Wọn lo yẹ ki akọroyin naa beere awọn ibeere to yẹ ko to le gbe abajade rẹ sita, ṣugbọn ti wọn sọ pe akọroyin naa ko ṣe bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI