MI O DA ÀJỌ ALAANU KANKAN SILẸ O - KASNATY PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 30, 2020

MI O DA ÀJỌ ALAANU KANKAN SILẸ O - KASNATY PARIWO SITA


Gbajugbaja sọrọsọrọ nni to filu Abéòkúta ṣe ibùgbé, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo ti sọ pe oun ko da àjọ alaanu kankan silẹ lati máa fi gba owo lọwọ àwọn èèyàn káàkiri, tó sì loun ko figba kan ri ronú nípa ẹ.

Kọlawọle ti púpọ awọn ololufẹ tun mọ sí Kasnaty lo sọrọ náà laipẹ yìí wí pé eto ori redio toun n ṣe loun tun n gbe káàkiri igboro, eyi to pe ni STREET VOICES WITH KASNATY.

O ni ohun tó dára ni ki èèyàn máa ronú lati wa awọn ọna tó lè fi dá yatọ láwùjọ, kò sì tún máa ronú nípa àwọn àgbékalẹ̀ tí wọpọ, idi pataki to loun tun fi gbe eto naa kalẹ.

F'awọn to ba mọ Kasnaty dáadáa, oun nikan ni sọrọsọrọ akọkọ ti yóò kọkọ gbé eto ori redio lọ sí gbàgede, tàwọn aráàlú yóò sì mọ gbogbo itu ti wọn n pa ninu yara igbohunsafẹfẹ, ìyẹn Studio.

AN EVENING WITH KASNATY AND FRIENDS lo pé eto naa, tó sì máa n waye ni gbogbo ọjọ Àìkú ti í ṣe Sannde to ba gbẹyin oṣù. Ọdún mẹta sí mẹrin gbáko lo fi ṣe eto naa nilu Abẹ́òkúta, tàwọn èèyàn sí n wa káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti wá a wòran láwọn asiko naa.

Kasnaty ninu ọrọ tẹsiwaju pe latigba toun ti pa ètò AN EVENING WITH KASNATY AND FRIENDS náà ti láwọn ololufẹ oun ti n béèrè pé ìgbà wo lòún yóò bẹrẹ pada, toun sí n jẹ ko ye wọn pe laipẹ ni.

O loun duro dè asiko Ọlọrun dáadáa, toun sí gbà itọni lati bẹrẹ eto STREET VOICES WITH KASNATY loṣu kẹrin ọdún yii, ti í ṣe 2020.

Bi ere bi awada lo sọ pé òun fi bẹrẹ pẹlú konilegbele ti ijọba pa laṣẹ f'awọn aráàlú lati dẹkun ajakalẹ arun COVID-19, to sì lo jẹ itẹwọgba.

Ọkùnrin tó rẹwa naa sọ pe ibi toun ti n lọ káàkiri láti máa bẹrẹ ọrọ lọwọ àwọn aráàlú ni Ọlọrun ti bẹrẹ sí í gbé àwọn alaanu dide f'awọn aráàlú ti ebi n pa, pàápàá iya kan ti wọn n pe ni Iya Saheed Onirọba.

Kasnaty ni Iya Saheed Onirọba lo tubọ jẹ kí eto naa di ilumọnka káàkiri àgbáyé, to fi di pe àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọn n gbe nilu Òyìnbó fi bẹrẹ sí í pé lati máa fún àwọn èèyàn lowo, bẹẹ lo tun ni wọn máa n pe oun lati máa lọ síbi tí wọn bá ti fẹẹ ṣaanu awọn èèyàn.

O ni oun ko gbe eto naa kalẹ gẹgẹ bí àjọ alaanu, bi ko ṣe eto ori redio loun gbe wa sita gbangba f'awọn aráàlú lati mọ bo ṣe n lọ nínú yàrá igbohunsafẹfẹ, to sì láwọn èèyàn máa n sọ ẹdun ọkan wọn.

Bakan naa lo jẹ ko di mímọ pé òun kò figba kankan ri tọrọ owo lọwọ ẹnikẹni lati fún àwọn èèyàn, tabi pe koun máa sọ pe kawon eeyan máa dá owó f'awọn toun n ba pade.

Fúnra àwọn tó ni wọn n wo oun káàkiri àgbáyé lati ori ikanni ayélujára tí fasibuuku ni wọn máa n fi owo ranṣẹ sòún, toun kò sí yọ nínú owo naa pamọ́ ri. O ni Ọlọrun ko ni jẹ koun di ẹni tó n jí owó olówó, tabi bẹrẹ sí í lù gbajuẹ káàkiri lẹyìn gbogbo òòrè ti Ọlọrun ti ṣe foun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI