Ẹ MAA ṢAANU AWỌN OBINRIN, WỌN ṢE PATAKI LAWUJỌ WA - OYEYẸMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 28, 2020

Ẹ MAA ṢAANU AWỌN OBINRIN, WỌN ṢE PATAKI LAWUJỌ WA - OYEYẸMI


Kọmiṣanna fun eto iṣuna n'ipinlẹ Kwara, Arabinrin Oyeyẹmi Ọlasunmbọ ti gba awọn eeyan, paapaa awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ lamọran lati maa ṣe ṣe iranlọwọ to ba yẹ f'awọn obinrin, paapaa awọn opo ti wọn ko ni ọkọ mọ, to jẹ pe adagbe-adafa ni wọn n ṣe. 
 
Oyeyẹmi lo sọrọ lasiko to n ro awọn obinrin ti wọn mọ nipa ọṣẹ ṣiṣe lagbara lagbegbe Odo-Ọwa, ijọba ibilẹ Oke-Ero, ipinlẹ Kwara laipẹ yii.
 
Bakan naa lo sọ pe yatọ si awọn obinrin, awọn ọdọ naa ṣe pataki lati maa ṣe iranlọwọ fun loore-koore fun idagbasoke eto ọrọ aje.
 
Lasiko to n gba ẹnu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọrọ, Ọnọrebu Oyeyẹmi sọ pe lara awọn ileri ati afojusun Gomina AbdulRazaq l'awọn ṣẹṣẹ n mu ẹyẹ rẹ bọ lapo, to si ni ijọba yo kọ ileeṣẹ kan t'awọn eeyan yoo ti maa kọ iṣẹ ọwọ, iyẹn Cottage Industries kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun kaakiri ipinlẹ yii.
 
O ni ipinnu naa wa ni nnkan bi oṣu meji sẹyin lẹyin ipade ati ijiroro toun ṣe pẹlu Kọmiṣanna fun ọrọ akanṣe iṣẹ ati igbokegbodo ọkọ, Rotimi Iliasu, ẹni to lo ṣi oju oun si eto toun n ṣe naa.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI