O MA ṢE O! IJAMBA MỌTO F'ẸMI ABIYAMỌ MEJI ṢOFO DANU L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 8, 2020

O MA ṢE O! IJAMBA MỌTO F'ẸMI ABIYAMỌ MEJI ṢOFO DANU L'OGUN

Ko din ni meji awọn abiyamọ meji ti wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọto to waye lagbegbe Fidiwọ loju ọna Eko si Ibadan lọjọ Aje, Mọndee ana, iyẹn ni nnkan bi aago mọkanla kọja ogun iṣẹju alẹ.
 
A gbọ pe ṣe ni mọto naa ti wọn pe ni Sharon Space Bus pẹlu nọmba idanimọ YEE 202 XA sare wọnu odo n'igba ti ijanu rẹ da iṣẹ silẹ lori ere.
 
Ọkunrin meji ati obinrin mẹrin pẹlu ọmọdebinrin kekere kan la gbọ pe wọn wa ninu mọto yii lasiko ijamba naa, t'awọn obinrin meji si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Yatọ si awọn meji ti wọn padanu ẹmi wọn yii, wọn l'awọn mẹrin tun farapa yannayanna kọja afẹnusọ, ti wọn si ti wa lọsibitu, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI