ỌGA AGBA N'ILEEṢẸ ỌKỌ OFURUFU TẸLẸ KU LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 2, 2020

ỌGA AGBA N'ILEEṢẸ ỌKỌ OFURUFU TẸLẸ KU LOJIJI


Muhtar Usman to jẹ ọga agba tẹlẹri n'ileeṣẹ ọkọ ofurufu orilẹ-ede yii, Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA) n'iroyin tẹ wa lọwọ wi pe o ti jade laye lẹni ọdun mẹtalelọgọta (63).
 
Alẹ ana ti i ṣe Tusidee la gbọ pe Usman ku si ọsibitu kan nilu Zaria, ipinlẹ Kaduna.
 
Ọdun 2014 si ọdun 2019 to kọja la gbọ pe Usman fi jẹ ọga agba (Director-General) n'ileeṣẹ NCAA.
 
Kete to f'ipo naa silẹ ni Aarẹ Muhammadu Buhari yan Balogun Musa Nuhu lati rọpo ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI