#ENDSARS : AWỌN OLOKOOWO TÍ WỌN PÀDÁNÙ LÁSÌKÒ IWỌDE BỌ́ S'ÁYÉ NÍ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 2, 2020

#ENDSARS : AWỌN OLOKOOWO TÍ WỌN PÀDÁNÙ LÁSÌKÒ IWỌDE BỌ́ S'ÁYÉ NÍ KWARA


Ìgbìmọ̀ oluwadii tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara yàn láti ṣe ìwádìí àwọn ileeṣẹ àti olokoowo kéékèèké tí wọn pàdánù lásìkò ifẹhonu hàn tí #ENDSARS tó wáyé l'oṣu kẹwàá ọdún yìí tí parí ìwádìí wọn. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, ìgbìmọ̀ náà tí igbá-kejì gómìnà, Kayọde Alabi lo ṣalaye wi pe awọn ti pari iwadii, t'awọn si ti mọ gbogbo awọn ileeṣẹ ati olokoowo keekeeke ti wọn padanu dukia ati ọja wọn sinu iwọde ifẹhonu han ti #ENDSARS naa lọjọ kẹtalelogun.
 
N'igba to n b'awọn eeyan sọrọ lanaa ti i ṣe Tusidee, Kayọde Alabi sọ pe ki i ṣe pe ipinnu igbimọ iwadii naa ni lati mọ iye awọn to fara gba ijamba naa, lati le mọ iru iranlọwọ t'ijọba yoo ṣe fun wọn.
 
O ni b'awọn ba gbe eto mi in kalẹ to yatọ si igbimọ naa, o ṣee ṣe k'awọn ti ijamba naa ko kan yọju, ki nnkan t'ijọba si fẹẹ ṣe f'awọn to fara kaaṣa naa ma to.
 
Bẹẹ lo sọ pe ki wọn maa reti esi lati ọdọ ijọba laipẹ.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI