VICTOR LU ABURO RẸ PA NITORI OWO ORI ABURO WỌN TÍ WỌN N JA SI I - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 3, 2020

VICTOR LU ABURO RẸ PA NITORI OWO ORI ABURO WỌN TÍ WỌN N JA SI I


Kayeefi nla gba a n'iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ f'awọn ara abule Umueje to wa lagbegbe Obinze, ijọba ibilẹ Owerri West Council, ipinlẹ Imo, pẹlu bi wọn ṣe ni Victor Iwu lu aburo rẹ, Bright Odi pa.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni ṣe ni Victor ati Bright bẹrẹ aawọ yii, ti wọn si n jijakadi lori bi wọn yoo ṣe pin awọn nkan ti wọn gba gẹgẹ bi owo ori aburo wọn obinrin.
 
Wọn ni ibi ti wọn ti n fa ọrọ naa ni Victor ti fun aburo rẹ, Bright ni ipa lẹpọn, tiyẹn ṣe bẹẹ ku.
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe ọjọ keji ni Bright pada ku, lẹyin ọpọlọpọ irora to ti jẹ, eyi ti wọn ni ko latunṣe.
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Orlando Ikeokwu fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni ọwọ awọn ti tẹ Victor, ati pe o ti wa nibi to ti n jẹwọ ẹṣẹ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI