WỌN TUN TI JI ABURO ỌKAN LARA AWỌN AṢOFIN IPINLẸ ỌYỌ GBE O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 25, 2020

WỌN TUN TI JI ABURO ỌKAN LARA AWỌN AṢOFIN IPINLẸ ỌYỌ GBE O


Ogun miliọnu l'awọn agbebọn ti wọn ji aburo ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyo, Ọnọrebu Sunkanmi Babalọla, iyẹn Tẹjumade babalọla gbe.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọjọ Aje ti i ṣe Mọnde ọsẹ yii la gbọ pe wọn ji Tẹjumade gbe lagbegbe Mọnatan nilu Ibadan.
 
Agbegbe Ẹgbẹda ni Ọnọrebu Sunkanmi Babalọla n ṣoju nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ.
 
Ṣọọbu la gbọ pe obinrin naa ti n bọ ko to di pe awọn agbebọn naa lọ dena rẹ pẹlu mọto lori ọkada to wa, ti wọn si ji i gbe wọnu igbo lọ. 
 
A gbọ pe ṣe ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ lasiko ti wọn fẹẹ ji obinrin naa gbe, ti wọn si fi tipa wọ ọ wọnu mọto wọn.
 
Ko pẹ ti wọn ji i gbe ni wọn bẹrẹ si i pe awọn mọlẹbi ẹ pe ki wọn mu ogun miliọnu naira wa lati gba Tẹjumade silẹ kuro lọwọ wọn.
 
Bo tilẹ jẹ pe alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi ti kọkọ sọ pe oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn to tun ti pada wa a sọ pe loootọ ni, ati pe awọn ti n ṣe iwadii lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI