AGBA OLOṢELU KAN YOO KU L'ỌDUN YII, AYAFI... - WOLII ỌLỌRUNMBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 4, 2021

AGBA OLOṢELU KAN YOO KU L'ỌDUN YII, AYAFI... - WOLII ỌLỌRUNMBẸ


Ọkan lara awọn Wolii orilẹ-ede yii, Wolii Michael Ọlọrunmbẹ ti ṣọọṣi God Liveth Ministry to wa ni Adiyan Ọlọmọwẹwẹ, Agbado ipinlẹ Eko ti sọ pe lara awọn nnkan ti Ọlọrun fi han oun pe yoo ṣẹlẹ lọdun 2021 ni pe Lara awon wolii Olorun ti won tun so asotele agba iyanu f'odun 2021 ti a wa yii ni pe gbajugbaja agba oloṣelu kan lorilẹ-ede yii yoo ku.
 
 
Wolii Michael Ọlọrunmbẹ sọ pe afi k'awọn ọmọ Naijiria at'awọn ololufẹ agba oloṣelu ba le gbadura fun un, ki ọkunrin naa maa ba a sọ ẹmi ara rẹ nu lojiji.
 
Bẹẹ lo sọ pe Ọlọrun ko fi agba oloṣelu naa han oun, idi ree to loun ko fi le da orukọ ẹ f'awọn eeyan lati gbadura fun un, ṣugbọn o ni o ṣe pataki lati maa gbadura f'awọn oloṣelu ti a ba fẹran.
 
Siwaju si i ni Wolii Ọlọrunmbẹ tun sọ pe "Ọdun igbega ati aṣeyọri ti ko wọpọ ni ọdun 2021 yii yoo jẹ f'awọn aladura patapata. A ni lati gbadura gidigidi ki ija nla ma ṣẹlẹ lorilẹ-ede yii laaarin oṣu kẹrin si oṣu karun-un ọdun yii.
 
"Awọn ọta ti mu agba oloṣelu kan lorilẹ-ede yii, awọn to sunmọ ọn gbọdọ kun fun adura nla ko ma jẹ pe ọdun yii ni yoo padanu ẹmi rẹ. Ọlọrun ko fi ẹni naa han mi.
 
"Konikaluku tẹpa mọ iṣẹ ọwọ rẹ daadaa, tori pe ọdun ikore nla ni yoo jẹ f'awọn olokoowo at'awọn arinrin ajo.
 
"K'ijọba ṣọra lati tẹri agbara ẹsin ba lorilẹ-ede yii, tori pe o ṣee ṣe ko fa ogun airo tẹlẹ. Ogun nla maa dide lorilẹ-ede kan nilẹ adulawọ, ara (bọmbu) ni wọn yoo maa fi ranṣẹ sira wọn, awọn ọmọ Naijiria ni lati gbadura ki ogun naa ma ba a wọle tọ wọn wa.
 
"Awọn ọkunrin gbọdọ fi ifẹ han si awọn iyawo wọn daadaa, wọn ko si gbọdọ jẹ ki wọn daamu pupọ, tori pe ẹmi awọn obinrin lo fẹẹ ṣiṣẹ lọdun yii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI