LẸYIN ỌDUN KAN GBAKO, GOMINA ABDULRAZAQ TU IGBIMỌ IṢAKOSO RẸ KA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 4, 2021

LẸYIN ỌDUN KAN GBAKO, GOMINA ABDULRAZAQ TU IGBIMỌ IṢAKOSO RẸ KA


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti tu igbimọ iṣakoso rẹ ka, to si ni igbesẹ naa bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun to kọja, iyẹn 2020.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye gbe jade lalẹ ọjọ Aiku ti i ṣe Sande ana lo ti sọ pe Gomina AbdulRazaq n pinnu lati yan igbimọ tuntun.

Bẹ o ba gbagbe, Ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2019 ni Gomina AbdulRazaq yan awọn igbimọ naa, to si bura fun wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe Akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Sabah Jubril nikan ni Gomina yọ silẹ ninu awọn igbimọ rẹ to tuka naa.
 
Gomina AbdulRazaq ti wa a paṣẹ pe k'awọn igbimọ naa ko gbogbo iwe at'awọn dukia ijọba to ba wa lọwọ wọn silẹ f'awọn ọga agba ẹka ileeṣẹ ti wọn wa, to si gbadura ọjọ iwaju rere fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI